Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Red Sea

47 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Solomoni ọba sì túnṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Geberi, tí ó wà ní ẹ̀bá Elati ní Edomu, létí Òkun Pupa.

  2. “Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Ejibiti; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa.

  3. Ìwọ rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí Farao, sí gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Ejibiti hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún ara à rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí.

  4. Ìwọ pín òkun níwájú wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá.

  5. Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ, wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá, níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀.

  6. Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.

  7. Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

  8. Nígbà tí àwọn baba wa wà ní Ejibiti, iṣẹ́ ìyanu rẹ kò yé wọn, wọn kò rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí ọ níbi Òkun, àní níbi Òkun Pupa.

  9. Ṣùgbọ́n o gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ láti jẹ́ kí agbára ńlá rẹ di mí mọ̀.

  10. O bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ; o sì mú wọn la ìbú já bí aginjù.

  11. O gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, láti ọwọ́ ọ̀tá ni o ti gbà wọ́n.

  12. Omi ya lu àwọn ọ̀tá wọn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó yè nínú wọn.

  13. iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun Pupa.

  14. Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  15. Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  16. Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  17. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun, ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,

  18. ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde, àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀, wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́, wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:

  19. Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.

  20. Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já.

  21. A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun.

  22. Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀ ni: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.