- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàgbà Júù tẹ̀síwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, ìran Iddo. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Israẹli àti àwọn àṣẹ Kirusi, Dariusi àti Artasasta àwọn ọba Persia pọ̀.
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àní, lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n ènìyàn kò róye rẹ̀.
Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn,
nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí; Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.
Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.
“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi.
Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan?
Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì ro ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”
Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.
Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.
Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.
Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé, “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.
Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.