Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peter

292 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

  2. Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìyìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.

  3. Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida.

  4. Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà.

  5. Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.

  6. Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe.

  7. Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè.

  8. Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”

  9. Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà, gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  10. Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó.

  11. Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè.

  12. Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.

  13. Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.

  14. Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́,

  15. ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun, ó bọ́ sí ojúran.

  16. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀.

  17. Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

  18. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”

  19. Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “Rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”

  20. Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

  21. Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

  22. Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  23. Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́

  24. wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”

  25. Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé,