Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Church (2)

158 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

  2. Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

  3. Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

  4. Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́, àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ, àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

  5. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé. Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, láti fi ọláńlá mi hàn.

  6. Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

  7. láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

  8. àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

  9. Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu; wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru. Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa, ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi,

  10. àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.

  11. Olúwa ti ṣe ìkéde títí dé òpin ilẹ̀ ayé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀! Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”

  12. A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́, ẹni ìràpadà Olúwa; a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri, ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.

  13. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”

  14. Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  15. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.

  16. Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.

  17. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”

  18. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’

  19. Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró. Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

  20. “Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn: ìtìjú ti bò wá lójú nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

  21. Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

  22. Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,

  23. títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

  24. Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

  25. Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.