Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Church (2): Unclassified scriptures relating to

130 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Unclassified scriptures relating to

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

  2. Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

  3. Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

  4. Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè Sioni, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.

  5. Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ.

  6. Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.

  7. Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

  8. nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́. Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀, kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní;

  9. àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀, àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

  10. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

  11. Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

  12. Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.

  13. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

  14. Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.

  15. Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.

  16. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

  17. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára; tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.

  18. Wo asà wa, Ọlọ́run; fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.

  19. Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ; èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  20. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin. Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;

  21. Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

  22. Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀, ìlú Ọlọ́run,

  23. “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

  24. Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ, “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀, àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”

  25. Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀: “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”