Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Children

257 ẹsẹ · 102 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀? Bí Olúwa ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’

  2. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”

  3. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Esra gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.

  4. Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú ibodè omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.

  5. Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.

  6. Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà

  7. wí pé, “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. Olúwa fi fún ni, Olúwa sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa.”

  8. Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára; Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,

  9. láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára, kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé, kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

  10. Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

  11. sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.

  12. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé: ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.

  13. Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró láé.

  14. Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.

  15. Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.

  16. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn; ojú kì yóò tì wọ́n, ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

  17. Orin fún ìgòkè. Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.

  18. Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.

  19. Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.

  20. Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù Olúwa.

  21. Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.

  22. Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.

  23. a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn, nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́ o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ. Ìran àwọn ìkà ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.

  24. Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀ kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.

  25. Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ, Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.