Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Children

257 ẹsẹ · 102 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  2. Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,

  3. “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

  4. Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”

  5. Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa.

  6. Olúwa sì wí fún un pé,

  7. “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ń sọ tọ̀nà. O gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

  8. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.

  9. Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.

  10. Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.

  11. Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀.

  12. Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí,

  13. baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀.

  14. Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.”

  15. Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.

  16. Èyí ní ìpín ẹ̀yà Manase tí í ṣe àkọ́bí Josẹfu, fún Makiri, àkọ́bí Manase. Makiri sì ni baba ńlá àwọn ọmọ Gileadi, tí ó ti gba Gileadi àti Baṣani nítorí pé àwọn ọmọ Makiri jẹ́ jagunjagun ńlá.

  17. Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Manase: ní agbo ilé Abieseri, Heleki, Asrieli, Ṣekemu, Heferi àti Ṣemida. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Manase ọmọ Josẹfu ní agbo ilé wọn.

  18. Nísinsin yìí Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  19. Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.

  20. Ìpín ilẹ̀ Manase sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gileadi àti Baṣani ìlà-oòrùn Jordani,

  21. nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Manase gba ìní ní àárín àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gileadi sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Manase.

  22. Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”

  23. Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú, Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”

  24. Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin, ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.

  25. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”