Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Children

257 ẹsẹ · 102 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé, “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.”

  2. Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé, “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

  3. Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá.

  4. Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ.” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

  5. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

  6. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.

  7. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á.

  8. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.

  9. “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ.

  10. Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.

  11. Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba.

  12. Olúwa sọ fún Mose pé,

  13. “Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákokò nǹkan oṣù rẹ̀.

  14. Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà.

  15. Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá.

  16. Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

  17. “ ‘Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá kọjá kí ó mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí àdàbà kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  18. Ó gbọdọ̀ fi wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa láti ṣe ètùtù fún obìnrin náà lẹ́yìn náà ni yóò di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. “ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún obìnrin tí ó bá bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin.

  19. Bí kò bá lágbára àti fi àgùntàn ṣe é, ó gbọdọ̀ le mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un. Òun yóò sì di mímọ́.’ ”

  20. Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

  21. “ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.

  22. Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  23. Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.

  24. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

  25. Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”