Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Children: Healing of

36 ẹsẹ · 102 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Healing of

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”

  2. Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.

  3. “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”

  4. Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”

  5. Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”

  6. Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀, ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.”

  7. Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.

  8. nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ. Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè.

  9. Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,

  10. Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.

  11. Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”

  12. Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”

  13. Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà.

  14. Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá, máa lọ ní Àlàáfíà.”

  15. Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”

  16. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà.

  18. Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”

  19. Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú.

  20. Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!”

  21. Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ.

  22. Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.

  23. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni.

  24. Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ.

  25. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”