Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Assyria

204 ẹsẹ · 59 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.

  2. Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí? Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga? Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!

  3. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.

  4. Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’

  5. “Ṣé o kò tí ì gbọ́? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀. Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀; ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ, pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di àkójọpọ̀ àwọn òkúta.

  6. Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì. Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.

  7. “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.

  8. Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá.

  9. “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.

  10. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.

  11. Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

  12. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.

  13. Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ; òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,” ni Olúwa wí.

  14. “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là, nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”

  15. O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,

  16. kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

  17. “Nítorí náà mo fi i sílẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ará Asiria, tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

  18. Wọ́n bọ́ ọ sí ìhòhò, wọ́n sì gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọn sì pa wọn pẹ̀lú idà. Ó di ẹni ìfisọ̀rọ̀ sọ láàrín àwọn obìnrin wọ́n sì fi ìyà jẹ ẹ́.

  19. “Àbúrò rẹ̀ Oholiba rí èyí, síbẹ̀ nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ̀, Ó ba ara rẹ jẹ́ ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.

  20. Òun náà ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ará Asiria àwọn gómìnà àti àwọn balógun, jagunjagun nínú aṣọ ogun, àwọn tí ń gun ẹṣin, gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin arẹwà.

  21. Mo rí i pé òun náà ba ara rẹ̀ jẹ́; àwọn méjèèjì rìn ojú ọ̀nà kan náà.

  22. “Ṣùgbọ́n ó tẹ̀síwájú nínú ṣíṣe panṣágà. O ri àwòrán àwọn ọkùnrin lára ògiri, àwòrán àwọn ara Kaldea àwòrán pupa,

  23. pẹ̀lú ìgbànú ni ìdí wọn àti àwọn ìgbàrí ni orí wọn; gbogbo wọn dàbí olórí kẹ̀kẹ́ ogun Babeli ọmọ ìlú Kaldea.

  24. Ní kété tí ó rí wọn, ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn, ó sì rán oníṣẹ́ sí wọn ni Kaldea.

  25. Àwọn ará Babeli wá sọ́dọ̀ rẹ̀, lórí ibùsùn ìfẹ́, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n bà á jẹ́. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn ní ìtìjú.