Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Assyria: Prophecies concerning

91 ẹsẹ · 59 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophecies concerning

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Efraimu ti yà kúrò ní Juda, yóò sì mú ọba Asiria wá.”

  2. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Ejibiti wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Asiria.

  3. Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.

  4. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹ fífẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò Eufurate, ọba Asiria, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.

  5. Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ abo màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.

  6. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàṣì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàṣì àti oyin.

  7. Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.

  8. Àwọn ènìyàn yóò máa lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà.

  9. Àti ní orí àwọn òkè kéékèèké tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń da màlúù lọ, àti ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀ fún àwọn àgùntàn kéékèèké.

  10. Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”

  11. Olúwa sì tún sọ fún mi pé,

  12. “Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini àti ọmọ Remaliah,

  13. ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le, tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn, àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀, yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,

  14. yóò sì gbá àárín Juda kọjá, yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn. Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀, ìwọ Emmanueli.”

  15. Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú, fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré. Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú!

  16. Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán, ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.

  17. “Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi, ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

  18. Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run, mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

  19. Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe, èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn; èrò rẹ̀ ni láti parun, láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.

  20. ‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.

  21. ‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi? Hamati kò ha dàbí i Arpadi, àti Samaria bí i Damasku?

  22. Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú, ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.

  23. Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ” Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

  24. Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.

  25. Nítorí ó sọ pé: “ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye. Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, mo sì ti kó ìṣúra wọn. Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.