- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 95
The Revelation
John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ìfihàn 2:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.
- Ìfihàn 2:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.
- Ìfihàn 2:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé. Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè.
- Ìfihàn 2:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani.
- Ìfihàn 2:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá, ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.
- Ìfihàn 2:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.
- Ìfihàn 2:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti sì angẹli ìjọ ni Pargamu kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní idà mímú olójú méjì.
- Ìfihàn 2:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.
- Ìfihàn 2:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.
- Ìfihàn 2:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikolatani pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra.
- Ìfihàn 2:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.
- Ìfihàn 2:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.
- Ìfihàn 2:18nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti sí angẹli ìjọ ní Tiatira kọ̀wé. Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára.
- Ìfihàn 2:19nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ.
- Ìfihàn 2:20nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ, nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà.
- Ìfihàn 2:21nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.
- Ìfihàn 2:22nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.
- Ìfihàn 2:23nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn, èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
- Ìfihàn 2:24nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tiatira, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pè ni ohun ìjìnlẹ̀ Satani, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín,
- Ìfihàn 2:25nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.
- Ìfihàn 2:26nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè:
- Ìfihàn 2:27nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi.
- Ìfihàn 2:28nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.
- Ìfihàn 2:29nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
- Ìfihàn 3:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi
“Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.