Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kronika 23:32nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.

  2. 1 Kronika 24:1nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

  3. 1 Kronika 24:2nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

  4. 1 Kronika 24:3nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.

  5. 1 Kronika 24:4nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari.

  6. 1 Kronika 24:5nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.

  7. 1 Kronika 24:6nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.

  8. 1 Kronika 24:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, èkejì sí Jedaiah,

  9. 1 Kronika 24:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,

  10. 1 Kronika 24:9nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,

  11. 1 Kronika 24:10nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    èkeje sì ni Hakosi, ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,

  12. 1 Kronika 24:11nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,

  13. 1 Kronika 24:12nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,

  14. 1 Kronika 24:13nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,

  15. 1 Kronika 24:14nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,

  16. 1 Kronika 24:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,

  17. 1 Kronika 24:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, ogún sì ni Jeheskeli,

  18. 1 Kronika 24:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,

  19. 1 Kronika 24:18nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.

  20. 1 Kronika 24:19nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.

  21. 1 Kronika 24:20nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Ìyókù àwọn ọmọ Lefi. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah.

  22. 1 Kronika 24:21nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.

  23. 1 Kronika 24:22nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti; láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.

  24. 1 Kronika 24:23nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.

  25. 1 Kronika 24:24nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Usieli: Mika; nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.