Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kronika 23:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: Laadani àti Ṣimei.

  2. 1 Kronika 23:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Laadani Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.

  3. 1 Kronika 23:9nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.

  4. 1 Kronika 23:10nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àti ọmọ Ṣimei: Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.

  5. 1 Kronika 23:11nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

  6. 1 Kronika 23:12nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.

  7. 1 Kronika 23:13nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Amramu. Aaroni àti Mose. A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé.

  8. 1 Kronika 23:14nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.

  9. 1 Kronika 23:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Mose: Gerṣomu àti Elieseri.

  10. 1 Kronika 23:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Gerṣomu: Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́.

  11. 1 Kronika 23:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Elieseri: Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́. Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.

  12. 1 Kronika 23:18nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.

  13. 1 Kronika 23:19nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.

  14. 1 Kronika 23:20nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Usieli: Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.

  15. 1 Kronika 23:21nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.

  16. 1 Kronika 23:22nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.

  17. 1 Kronika 23:23nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.

  18. 1 Kronika 23:24nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.

  19. 1 Kronika 23:25nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé,

  20. 1 Kronika 23:26nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀.”

  21. 1 Kronika 23:27nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  22. 1 Kronika 23:28nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.

  23. 1 Kronika 23:29nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n.

  24. 1 Kronika 23:30nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́.

  25. 1 Kronika 23:31nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi

    Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.