circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 21:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́ láti òní lọ àti títí láé.” Lójúkan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.
- Matiu 21:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnu yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíá?”
- Matiu 21:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀.
- Matiu 21:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”
- Matiu 21:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu wọ tẹmpili, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí?”
- Matiu 21:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.
- Matiu 21:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’
- Matiu 21:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”
- Matiu 21:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.
- Matiu 21:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’
- Matiu 21:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.
- Matiu 21:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.
- Matiu 21:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?” Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.” Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín.
- Matiu 21:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”
- Matiu 21:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn, Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.
- Matiu 21:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.
- Matiu 21:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta.
- Matiu 21:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
- Matiu 21:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’
- Matiu 21:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’
- Matiu 21:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.
- Matiu 21:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?”
- Matiu 21:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”
- Matiu 21:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú Ìwé Mímọ́ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; iṣẹ́ Olúwa ni èyí, ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?
- Matiu 21:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.