Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 20:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.

  2. Matiu 20:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’

  3. Matiu 20:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà.

  4. Matiu 20:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’

  5. Matiu 20:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ “Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’

  6. Matiu 20:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’

  7. Matiu 20:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan.

  8. Matiu 20:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.

  9. Matiu 20:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà,

  10. Matiu 20:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’

  11. Matiu 20:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan.

  12. Matiu 20:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó ní, gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.

  13. Matiu 20:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’

  14. Matiu 20:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”

  15. Matiu 20:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé,

  16. Matiu 20:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú.

  17. Matiu 20:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti náà án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”

  18. Matiu 20:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.

  19. Matiu 20:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

  20. Matiu 20:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

  21. Matiu 20:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

  22. Matiu 20:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí.

  23. Matiu 20:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba.

  24. Matiu 20:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni,

  25. Matiu 20:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin.