circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 22:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè,
- Matiu 22:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.
- Matiu 22:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrín wa níhìn-ín yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú ní àìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.
- Matiu 22:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títí tí òun fi di ìyàwó ẹni keje.
- Matiu 22:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú.
- Matiu 22:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?”
- Matiu 22:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ Ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.
- Matiu 22:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run.
- Matiu 22:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé:
- Matiu 22:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”
- Matiu 22:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.
- Matiu 22:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ.
- Matiu 22:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí.
- Matiu 22:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”
- Matiu 22:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’
- Matiu 22:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ.
- Matiu 22:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’
- Matiu 22:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”
- Matiu 22:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé,
- Matiu 22:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”
- Matiu 22:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,
- Matiu 22:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’
- Matiu 22:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
- Matiu 22:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.
- Matiu 23:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,