Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 20:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì.

  2. Johanu 20:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì.

  3. Johanu 20:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀.

  4. Johanu 20:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀.

  5. Johanu 20:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀.

  6. Johanu 20:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́.

  7. Johanu 20:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    (Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú).

  8. Johanu 20:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

  9. Johanu 20:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì.

  10. Johanu 20:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí.

  11. Johanu 20:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?” Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

  12. Johanu 20:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni.

  13. Johanu 20:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?” Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”

  14. Johanu 20:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún un pé, “Maria!” Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”).

  15. Johanu 20:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi. Ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín, àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

  16. Johanu 20:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

  17. Johanu 20:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”

  18. Johanu 20:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

  19. Johanu 20:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.”

  20. Johanu 20:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́!

  21. Johanu 20:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”

  22. Johanu 20:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé.

  23. Johanu 20:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!” Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

  24. Johanu 20:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.”

  25. Johanu 20:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”