Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 19:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí, nítorí ibi tí a gbé kan Jesu mọ́ àgbélébùú súnmọ́ etí ìlú, a sì kọ ọ́ ní èdè Heberu àti Latin, àti ti Giriki.

  2. Johanu 19:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù,’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.”

  3. Johanu 19:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.

  4. Johanu 19:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

  5. Johanu 19:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.” Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.

  6. Johanu 19:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú,

  7. Johanu 19:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!”

  8. Johanu 19:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.

  9. Johanu 19:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.”

  10. Johanu 19:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu.

  11. Johanu 19:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.

  12. Johanu 19:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà), nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.

  13. Johanu 19:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, àwọn ọmọ-ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀.

  14. Johanu 19:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀,

  15. Johanu 19:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójúkan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.

  16. Johanu 19:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin ba à lè gbàgbọ́.

  17. Johanu 19:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.”

  18. Johanu 19:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

  19. Johanu 19:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò, Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ.

  20. Johanu 19:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún lita.

  21. Johanu 19:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.

  22. Johanu 19:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí.

  23. Johanu 19:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.

  24. Johanu 20:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì.

  25. Johanu 20:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”