Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 18:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́, kín ní ìwọ ṣe?”

  2. Johanu 18:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dáhùn wí pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Ìbá ṣe pé ìjọba mi jẹ́ ti ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ìbá jà, kí a má ba à fi mí lé àwọn Júù lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba mi kì í ṣe láti ìhín lọ.”

  3. Johanu 18:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”

  4. Johanu 18:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.

  5. Johanu 18:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá, nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”

  6. Johanu 18:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.

  7. Johanu 19:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án.

  8. Johanu 19:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́.

  9. Johanu 19:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

  10. Johanu 19:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.”

  11. Johanu 19:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ọkùnrin náà!”

  12. Johanu 19:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà nígbà tí àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn oníṣẹ́ rí i, wọ́n kígbe wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un fún ara yín, kí ẹ sì kàn án mọ́ àgbélébùú: nítorí èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.”

  13. Johanu 19:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”

  14. Johanu 19:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.

  15. Johanu 19:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn.

  16. Johanu 19:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

  17. Johanu 19:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá, nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.”

  18. Johanu 19:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”

  19. Johanu 19:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jesu jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Heberu, Gabata.

  20. Johanu 19:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà: Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

  21. Johanu 19:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.” Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.”

  22. Johanu 19:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.

  23. Johanu 19:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnra rẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta.

  24. Johanu 19:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.

  25. Johanu 19:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, Jesu ti Nasareti Ọba àwọn Júù.