Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 13:14nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”

  2. Jeremiah 13:15nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀, ẹ má ṣe gbéraga, nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

  3. Jeremiah 13:16nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ó tó mú òkùnkùn wá, àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé lórí òkè tí ó ṣókùnkùn. Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri.

  4. Jeremiah 13:17nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

  5. Jeremiah 13:18nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Sọ fún ọba àti ayaba pé, “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín, adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”

  6. Jeremiah 13:19nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

  7. Jeremiah 13:20nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn.

  8. Jeremiah 13:21nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

  9. Jeremiah 13:22nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

  10. Jeremiah 13:23nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

  11. Jeremiah 13:24nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.

  12. Jeremiah 13:25nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ìpín tìrẹ; tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,” ni Olúwa wí, “Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.

  13. Jeremiah 13:26nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    N ó sí aṣọ lójú rẹ, kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta—

  14. Jeremiah 13:27nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àìlójútì panṣágà rẹ! Mo ti rí ìwà ìríra rẹ, lórí òkè àti ní pápá. Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu! Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

  15. Jeremiah 14:1nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

  16. Jeremiah 14:2nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Juda káàánú, àwọn ìlú rẹ̀ kérora wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn, igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.

  17. Jeremiah 14:3nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn.

  18. Jeremiah 14:4nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà; ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn.

  19. Jeremiah 14:5nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko.

  20. Jeremiah 14:6nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

  21. Jeremiah 14:7nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ.

  22. Jeremiah 14:8nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

  23. Jeremiah 14:9nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀.

  24. Jeremiah 14:10nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

  25. Jeremiah 14:11nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.