circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 15:15nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Ó yé ọ, ìwọ Olúwa; rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi. Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ; nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
- Jeremiah 15:16nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
- Jeremiah 15:17nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
- Jeremiah 15:18nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
- Jeremiah 15:19nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.
- Jeremiah 15:20nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 15:21nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
- Jeremiah 16:1nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
- Jeremiah 16:2nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.”
- Jeremiah 16:3nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn.
- Jeremiah 16:4nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”
- Jeremiah 16:5nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 16:6nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn.
- Jeremiah 16:7nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.
- Jeremiah 16:8nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu.
- Jeremiah 16:9nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.
- Jeremiah 16:10nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’
- Jeremiah 16:11nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.
- Jeremiah 16:12nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Wò ó bí gbogbo yín ṣe ń rìn, olúkúlùkù yín nínú agídí ọkàn búburú rẹ̀, dípò kí ẹ fi gbọ́ tèmi.
- Jeremiah 16:13nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí baba yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn ọlọ́run kéékèèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’
- Jeremiah 16:14nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’
- Jeremiah 16:15nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.
- Jeremiah 16:16nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
“Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta.
- Jeremiah 16:17nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi.
- Jeremiah 16:18nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi
Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”