Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 14:12nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

  2. Jeremiah 14:13nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

  3. Jeremiah 14:14nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.

  4. Jeremiah 14:15nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.

  5. Jeremiah 14:16nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

  6. Jeremiah 14:17nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé: “ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé ní ọ̀sán àti ní òru láìdá; nítorí tí a ti ṣá wúńdíá, ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá pẹ̀lú lílù bolẹ̀.

  7. Jeremiah 14:18nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

  8. Jeremiah 14:19nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí.

  9. Jeremiah 14:20nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

  10. Jeremiah 14:21nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á.

  11. Jeremiah 14:22nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀? Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí? Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa. Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

  12. Jeremiah 15:1nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!

  13. Jeremiah 15:2nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’

  14. Jeremiah 15:3nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.

  15. Jeremiah 15:4nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

  16. Jeremiah 15:5nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu? Ta ni yóò dárò rẹ? Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?

  17. Jeremiah 15:6nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.

  18. Jeremiah 15:7nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ, Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.

  19. Jeremiah 15:8nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn Òkun lọ. Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójijì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.

  20. Jeremiah 15:9nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni Olúwa wí.

  21. Jeremiah 15:10nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi, ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà! Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.

  22. Jeremiah 15:11nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ pé, “Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó; dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.

  23. Jeremiah 15:12nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ?

  24. Jeremiah 15:13nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.

  25. Jeremiah 15:14nǹkan bí 605 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”