Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ìdílé ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n ti hó lé ọ lórí. Má ṣe gbà wọ́n gbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

  2. Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

  3. Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.

  4. Ogún mi kò ha ti rí sí mi bí ẹyẹ kannakánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ, ẹ mú wọn wá jẹ.

  5. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

  6. A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.

  7. Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà; kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.

  8. Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

  9. Jeremiah 12:14nǹkan bí 603 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn.

  10. Jeremiah 12:15nǹkan bí 603 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.

  11. Jeremiah 12:16nǹkan bí 603 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi.

  12. Jeremiah 12:17nǹkan bí 603 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.

  13. Jeremiah 13:1nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.”

  14. Jeremiah 13:2nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

  15. Jeremiah 13:3nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì,

  16. Jeremiah 13:4nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.”

  17. Jeremiah 13:5nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

  18. Jeremiah 13:6nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.”

  19. Jeremiah 13:7nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

  20. Jeremiah 13:8nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

  21. Jeremiah 13:9nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu.

  22. Jeremiah 13:10nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.

  23. Jeremiah 13:11nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

  24. Jeremiah 13:12nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

  25. Jeremiah 13:13nǹkan bí 599 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu.