circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 17:23nǹkan bí 611 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.
- Jeremiah 17:24nǹkan bí 611 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà.
- Jeremiah 17:25nǹkan bí 611 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.
- Jeremiah 17:26nǹkan bí 611 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa.
- Jeremiah 17:27nǹkan bí 611 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe:
- Jeremiah 18:2nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
“Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.”
- Jeremiah 18:3nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.
- Jeremiah 18:4nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.
- Jeremiah 18:5nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
- Jeremiah 18:6nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli.
- Jeremiah 18:7nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun,
- Jeremiah 18:8nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.
- Jeremiah 18:9nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan.
- Jeremiah 18:10nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.
- Jeremiah 18:11nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’
- Jeremiah 18:12nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”
- Jeremiah 18:13nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
- Jeremiah 18:14nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
- Jeremiah 18:15nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán, tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn, àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́, àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.
- Jeremiah 18:16nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di nǹkan ẹ̀gàn títí láé, gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọn yóò sì mi orí wọn.
- Jeremiah 18:17nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn, Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn. Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn ní ọjọ́ àjálù wọn.”
- Jeremiah 18:18nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”
- Jeremiah 18:19nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
- Jeremiah 18:20nǹkan bí 608 ṣáájú Kristi
Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi. Rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.