circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 20:8nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Nígbàkígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta èmi á sọ nípa ipá àti ìparun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
- Jeremiah 20:9nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi nínú egungun mi, agara dá mi ní inú mi nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
- Jeremiah 20:10nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo. Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”
- Jeremiah 20:11nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù. Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀. Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
- Jeremiah 20:12nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní, jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.
- Jeremiah 20:13nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Kọrin sí Olúwa! Fi ìyìn fún Olúwa! Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.
- Jeremiah 20:14nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
- Jeremiah 20:15nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi, tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé, “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”
- Jeremiah 20:16nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀, ariwo ogun ní ọ̀sán.
- Jeremiah 20:17nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Nítorí kò pa mí nínú, kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi, kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.
- Jeremiah 20:18nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn, láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀ àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?
- Jeremiah 21:1nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá nígbà tí ọba Sedekiah rán Paṣuri ọmọ Malkiah àti àlùfáà Sefaniah ọmọ Maaseiah sí i; wọ́n wí pé:
- Jeremiah 21:2nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadnessari ọba Babeli ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”
- Jeremiah 21:3nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Jeremiah dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekiah,
- Jeremiah 21:4nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.
- Jeremiah 21:5nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle.
- Jeremiah 21:6nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.
- Jeremiah 21:7nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ pé lẹ́yìn èyí, èmi yóò fi Sedekiah ọba Juda, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn, àti àwọn tí ó kù ní ìlú yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn àti lọ́wọ́ idà, àti lọ́wọ́ ìyàn; èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé ọwọ́ àwọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn, òun yóò sì fi ojú idà pa wọ́n, kì yóò sì dá wọn sí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ní ìyọ́nú tàbí ṣàánú wọn.’
- Jeremiah 21:8nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.
- Jeremiah 21:9nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.
- Jeremiah 21:10nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’
- Jeremiah 21:11nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
- Jeremiah 21:12nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ: “ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀; yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná. Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á.
- Jeremiah 21:13nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu, ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí. Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá? Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?”
- Jeremiah 21:14nǹkan bí 589 ṣáájú Kristi
Èmi yóò jẹ ọ ní ìyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni Olúwa wí. Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀; yóò si jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”