- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Kronika 18:28nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi.
- 2 Kronika 18:29nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.
- 2 Kronika 18:30nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.”
- 2 Kronika 18:31nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, Olúwa sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,
- 2 Kronika 18:32nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró.
- 2 Kronika 18:33nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.”
- 2 Kronika 18:34nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú.
- 2 Kronika 19:1nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu,
- 2 Kronika 19:2nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Jehu aríran, ọmọ Hanani jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Ṣé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra Olúwa? Nítorí èyí, ìbínú Olúwa wà lórí wa.
- 2 Kronika 19:3nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà Aṣerah kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.”
- 2 Kronika 19:4nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Jehoṣafati sì ń gbé ní Jerusalẹmu ó sì jáde lọ padà láàrín àwọn ènìyàn láti Beerṣeba dé òkè ìlú Efraimu, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn.
- 2 Kronika 19:5nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda.
- 2 Kronika 19:6nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.
- 2 Kronika 19:7nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”
- 2 Kronika 19:8nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, Jehoṣafati yan díẹ̀ lára àwọn Lefi, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Israẹli si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
- 2 Kronika 19:9nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé. “Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù Olúwa.
- 2 Kronika 19:10nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń sàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, pa á láṣẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyí, ìwọ kì yóò sì jẹ̀bi.
- 2 Kronika 19:11nǹkan bí 896 ṣáájú Kristi
“Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”
Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati.
Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe En-Gedi).
Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda.
Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a.
Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.
O sì wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.
Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?