Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 16:11nǹkan bí 955 ṣáájú Kristi

    Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli.

  2. 2 Kronika 16:12nǹkan bí 916 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.

  3. 2 Kronika 16:13nǹkan bí 914 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀,

  4. 2 Kronika 16:14nǹkan bí 914 ṣáájú Kristi

    wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.

  5. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ ó sì mú ara rẹ̀ lágbára sí lórí Israẹli.

  6. Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Juda ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Juda àti nínú ìlú Efraimu tí Asa baba rẹ̀ ti gbà.

  7. Olúwa sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali.

  8. Ṣùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Israẹli.

  9. 2 Kronika 17:5nǹkan bí 913 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  10. 2 Kronika 17:6nǹkan bí 913 ṣáájú Kristi

    Ọkàn rẹ̀ sì gbé sókè si ọ̀nà Olúwa, pẹ̀lúpẹ̀lú, ó sì mú ibi gíga wọn àti ère òrìṣà Aṣerah kúrò ní Juda.

  11. 2 Kronika 17:7nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bene-Haili, Obadiah, Sekariah, Netaneli, Mikaiah láti máa kọ́ ni nínú ìlú Juda.

  12. 2 Kronika 17:8nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi, àní Ṣemaiah, Netaniah, Sebadiah, Asaheli, Ṣemiramotu, Jehonatani, Adonijah, Tobijah àti Tobu-Adonijah àti àwọn àlùfáà Eliṣama àti Jehoramu.

  13. 2 Kronika 17:9nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Wọ́n ń kọ́ ni ní agbègbè Juda, wọ́n mú ìwé òfin Olúwa wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Juda wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.

  14. 2 Kronika 17:10nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Ìbẹ̀rù Olúwa bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Juda ká, dé bi pé wọn kò bá Jehoṣafati jagun.

  15. 2 Kronika 17:11nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Lára àwọn ará Filistini, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jehoṣafati, àwọn ará Arabia sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún un, ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) àgbò àti ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) òbúkọ.

  16. 2 Kronika 17:12nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Jehoṣafati sì ń di alágbára nínú agbára sí i, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìṣúra púpọ̀ ní Juda

  17. 2 Kronika 17:13nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Ó sì ní ìṣúra ní ìlú Juda. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jerusalẹmu.

  18. 2 Kronika 17:14nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nìwọ̀nyí. Láti Juda, àwọn olórí ìpín kan ti ẹgbẹ̀rún (1,000): Adina olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) alágbára akọni ọkùnrin.

  19. 2 Kronika 17:15nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Èkejì, Jehohanani olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) ọkùnrin;

  20. 2 Kronika 17:16nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    àtẹ̀lé Amasiah ọmọ Sikri, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000).

  21. 2 Kronika 17:17nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Láti ọ̀dọ̀ Benjamini: Eliada, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;

  22. 2 Kronika 17:18nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    àtẹ̀lé Jehosabadi, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun.

  23. 2 Kronika 17:19nǹkan bí 912 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwájú ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Juda.

  24. 2 Kronika 18:1nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀.

  25. 2 Kronika 18:2nǹkan bí 897 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi.