- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 970–930 BC
Solomon & The Temple
Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Ọba 8:58nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Kí ó fa ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, láti máa rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti àṣẹ rẹ̀, àti ìlànà rẹ̀, tí ó ti pàṣẹ fún àwọn baba wa.
- 1 Ọba 8:59nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú Olúwa, kí ó wà nítòsí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Israẹli ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́,
- 1 Ọba 8:60nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
kí gbogbo ènìyàn ayé lè mọ̀ pé Olúwa òun ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn.
- 1 Ọba 8:61nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.”
- 1 Ọba 8:62nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa.
- 1 Ọba 8:63nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.
- 1 Ọba 8:64nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárín tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.
- 1 Ọba 8:65nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.
- 1 Ọba 8:66nǹkan bí 1004 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Israẹli ènìyàn rẹ̀.
- 1 Ọba 9:1nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe,
- 1 Ọba 9:2nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni.
- 1 Ọba 9:3nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wí fún un pé, “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.
- 1 Ọba 9:4nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́,
- 1 Ọba 9:5nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’
- 1 Ọba 9:6nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,
- 1 Ọba 9:7nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè.
- 1 Ọba 9:8nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’
- 1 Ọba 9:9nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, tí ó mú àwọn baba wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti gbá ọlọ́run mìíràn mú, wọ́n ń bọ wọ́n, wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyìí tí Olúwa ṣe mú gbogbo ìjàǹbá yìí wá sórí wọn.’ ”
- 1 Ọba 9:10nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.
- 1 Ọba 9:11nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.
- 1 Ọba 9:12nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.
- 1 Ọba 9:13nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí.
- 1 Ọba 9:14nǹkan bí 991 ṣáájú Kristi
Hiramu sì ti fi ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.
- 1 Ọba 9:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri.
- 1 Ọba 9:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ.