Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Heberu 10:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì, nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí.

  2. Heberu 10:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere,

  3. Heberu 10:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

  4. Heberu 10:26nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

  5. Heberu 10:27nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run.

  6. Heberu 10:28nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.

  7. Heberu 10:29nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́.

  8. Heberu 10:30nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé, Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.”

  9. Heberu 10:31nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

  10. Heberu 10:32nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà;

  11. Heberu 10:33nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si.

  12. Heberu 10:34nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  13. Heberu 10:35nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

  14. Heberu 10:36nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.

  15. Heberu 10:37nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí, “Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara.

  16. Heberu 10:38nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n, “Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn, ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

  17. Heberu 10:39nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.

  18. Heberu 11:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń retí, ìjẹ́rìí ohun tí a kò rí.

  19. Heberu 11:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà àtijọ́ ní ẹ̀rí rere.

  20. Heberu 11:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.

  21. Heberu 11:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀, àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.

  22. Heberu 11:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Enoku ní ipò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sì rí i mọ́, nítorí Ọlọ́run ṣí i ní ipò padà ṣáájú ìṣípò padà rẹ̀, a jẹ́rìí yìí sí i pé o wu Ọlọ́run.

  23. Heberu 11:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

  24. Heberu 11:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tí ì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

  25. Heberu 11:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè.