Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Efesu 5:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.

  2. Efesu 5:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.

  3. Efesu 5:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́.

  4. Efesu 5:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà (tí í ṣé abọ̀rìṣà), tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run.

  5. Efesu 5:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.

  6. Efesu 5:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.

  7. Efesu 5:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀

  8. Efesu 5:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    (nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́).

  9. Efesu 5:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.

  10. Efesu 5:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí.

  11. Efesu 5:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀.

  12. Efesu 5:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni.

  13. Efesu 5:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

  14. Efesu 5:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n;

  15. Efesu 5:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    ẹ máa ra ìgbà padà, nítorí búburú ní àwọn ọjọ́.

  16. Efesu 5:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí.

  17. Efesu 5:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

  18. Efesu 5:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa.

  19. Efesu 5:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.

  20. Efesu 5:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  21. Efesu 5:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa.

  22. Efesu 5:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀.

  23. Efesu 5:24nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.

  24. Efesu 5:25nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.

  25. Efesu 5:26nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí.