Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Efesu 3:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;

  2. Efesu 3:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere.

  3. Efesu 3:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

  4. Efesu 3:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà;

  5. Efesu 3:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi.

  6. Efesu 3:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,

  7. Efesu 3:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa.

  8. Efesu 3:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.

  9. Efesu 3:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.

  10. Efesu 3:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi.

  11. Efesu 3:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.

  12. Efesu 3:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

  13. Efesu 3:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;

  14. Efesu 3:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́.

  15. Efesu 3:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.

  16. Efesu 3:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.

  17. Efesu 3:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.

  18. Efesu 4:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí.

  19. Efesu 4:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.

  20. Efesu 4:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

  21. Efesu 4:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín.

  22. Efesu 4:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan.

  23. Efesu 4:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.

  24. Efesu 4:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òsùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi.

  25. Efesu 4:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà a wí pé: “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga, ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn, ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”