- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Romu 14:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹ gba ẹni tí ó bá ṣe àìlera ní ìgbàgbọ́ mọ́ra, kí ẹ má ṣe tọpinpin ìṣeyèméjì rẹ̀.
- Romu 14:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan.
- Romu 14:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi nítorí Ọlọ́run ti gbà á.
- Romu 14:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.
- Romu 14:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀.
- Romu 14:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.
- Romu 14:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó kú fún ara rẹ̀.
- Romu 14:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe.
- Romu 14:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.
- Romu 14:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
- Romu 14:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: “ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí, ‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi; gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”
- Romu 14:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.
- Romu 14:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín.
- Romu 14:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún.
- Romu 14:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé.
- Romu 14:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ ohun tí ẹ mọ̀ sí rere ní búburú.
- Romu 14:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìjọba ọ̀run kì í ṣe jíjẹ àti mímu, bí kò ṣe nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Ẹ̀mí Mímọ́,
- Romu 14:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.
- Romu 14:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.
- Romu 14:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀.
- Romu 14:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú.
- Romu 14:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn.
- Romu 14:23nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.
- Romu 15:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa.
- Romu 15:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró.