Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”

  2. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.

  3. Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Aijaloni.”

  4. Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli pa wọ́n ní ìpakúpa wọ́n sì pa gbogbo ọmọ-ogun àwọn ọba márààrún run, àyàfi àwọn díẹ̀ tí wọ́n tiraka láti dé ìlú olódi wọn.

  5. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì padà sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní ibùdó ogun ní Makkeda ní àlàáfíà, kò sí àwọn tí ó dábàá láti tún kọlu Israẹli.

  6. Àwọn ará Israẹli sì kó gbogbo ìkógun àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátápátá, kò sí ẹni tí ó wà láààyè.

  7. Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Israẹli ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hifi tí wọ́n ń gbé ní Gibeoni, gbogbo wọn ló bá a jagun.

  8. Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu.

  9. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

  10. Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

  11. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:

  12. “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,

  13. Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.

  14. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀.

  15. Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kenaani, tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Israẹli pín fún wọn.

  16. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kenaani sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátápátá.

  18. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

  19. ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ Israẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn.

  20. Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?

  21. Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

  22. Nígbà tí wọ́n ti parí pínpín ilẹ̀ náà ní ìpín ti olúkúlùkù, àwọn ará Israẹli fún Joṣua ọmọ Nuni ní ìní ní àárín wọn,

  23. Wọ̀nyí ni àwọn ilẹ̀ tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti àwọn olórí ẹ̀yà agbo ilé Israẹli fi ìbò pín ní Ṣilo ní iwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Báyìí ni wọ́n parí pínpín ilẹ̀ náà.

  24. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mose,

  25. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé ní àárín wọn tí ó ṣèèṣì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.