Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

  3. “Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi.

  4. Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù, ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi.

  5. Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ, Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga. Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.

  6. Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún, Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.

  7. Beari igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà, Èmi yóò bá wọn jà bí? Èmi yóò sì fà wọ́n ya bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya bi ẹranko búburú ni èmi yóò fa wọn ya.

  8. “A ti pa ọ́ run, ìwọ Israẹli, nítorí pé ìwọ lòdì sí mi, ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.

  9. Níbo ni ọba rẹ gbé wà nísinsin yìí kí ó bá à le gbà ọ là? Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà, àwọn tí ẹ sọ pé, ‘Fún wa ní ọba àti ọmọ-aládé’?

  10. Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín ní ọba, nínú ìbínú gbígbóná mi, mo sì mú un kúrò.

  11. “Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú, ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.

  12. Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀ afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yóò wá, yóò fẹ́ wá láti inú aginjù orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ kànga rẹ̀ yóò gbẹ pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀.

  13. Ará Samaria gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn. Wọn ó ti ipa idà ṣubú; a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”

  14. Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!

  15. Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí Olúwa. Ẹ sọ fún un pé, “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ

  16. Asiria kò le gbà wá là; a kò ní í gorí ẹṣin ogun. A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé, ‘Àwọn ni òrìṣà wa’ sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.”

  17. “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  18. Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli, wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì. Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò.

  19. Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

  20. Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.

  21. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.

  22. Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.

  23. Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.

  24. A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé Olúwa. Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa.

  25. Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.