God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá; wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn, Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run. Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀, Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.
Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn. Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára, síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo; wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́. Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú nítorí ìrunú ahọ́n wọn. Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
Israẹli kígbe pè mí, ‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn.
Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria! Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
Israẹli ni wọ́n ti wá! Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é, àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè, Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí. Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.
Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀, ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn. Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọn yóò padà sí Ejibiti.
Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Efraimu. Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.
Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
“Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù. Mo rí àwọn baba yín, bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ, wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni, ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́.
Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn. Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!