God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀, wọ́n sì ti fi ara wọn
Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu Israẹli kò sì pamọ́ fún mi Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè Israẹli sì ti díbàjẹ́.
“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn, wọn kò sì mọ Olúwa.
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ. Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli, Mo sọ ohun tí ó dájú.
Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi.
Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu, Mo sì dàbí ìdin ara Juda.
Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa; ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, yóò jáde; yóò tọ̀ wá wá bí òjò, bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.
Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù ní ilé Israẹli. Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Israẹli sì di aláìmọ́.
“Àti fún ìwọ, Juda, a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;