Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú.

  2. Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúúsù. Ní àárín gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà.

  3. Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn ọmọ Sadoku tí wọn jẹ́ olóòtítọ́ nínú sí sìn mí, tiwọn kò sì ṣáko lọ bí ti àwọn Lefi ṣe ṣe nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ.

  4. Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí pààrọ̀ ọ̀kankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ̀ náà, a kò sì gbọdọ̀ fi fún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

  5. “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn,” ní Olúwa Olódùmarè wí.

  6. “Jíjìnnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ìgbọ̀nwọ́. “Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́: ‘Olúwa wà níbẹ̀.’ ”

  7. Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.

  8. Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà,

  9. Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.

  10. Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli.

  11. Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run

  12. Daniẹli wí pé: “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé; tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.

  13. Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

  14. Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.

  15. Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  16. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

  17. “Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

  18. Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ;

  19. ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí wúrà náà.

  20. “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”

  21. Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́. “Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”

  22. Ọba wí fún Daniẹli pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àṣírí, nítorí tí ìwọ lè fi àṣírí yìí hàn.”

  23. Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

  24. Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba.

  25. Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ ọlọ́run.”