God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Daniẹli jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Daniẹli jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé, ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli.
Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là;
“Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná.
Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá. Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀.
“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀.
títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba.
Yóò sọ̀rọ̀ odi sí Ọ̀gá-ògo, yóò sì pọ́n ẹni mímọ́ lójú, yóò sì gbèrò láti yí ìgbà àti òfin padà. A ó fi àwọn ẹni mímọ́ lé e lọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, ní ọdún méjì àti ààbọ̀.
Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn Ọ̀gá-ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’
ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ-aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ààyè ibi mímọ́ rẹ̀.
Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro.
Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé: “Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.
Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.
“Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.
Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.
Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i;
àwa kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.
Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí.
Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ.
Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; síbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ràn sí i.
“Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú.
Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.