God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Wọn yóò sì fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín mímọ́ àti àìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, wọn yóò sì fihàn wọ́n bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́.
“ ‘Nínú èyíkéyìí èdè-àìyedè, àwọn àlùfáà ní yóò dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn, wọn sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi ní mímọ́.
Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti ṣe ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí ó rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
“ ‘Èmi ni yóò jẹ́ ogún kan ṣoṣo tí àwọn àlùfáà yóò ní. Ẹ kì yóò fún wọn ni ìpín kankan ní Israẹli, Èmi ni yóò jẹ́ ìní wọn.
“ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́.
Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.
Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.
“ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.
Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí.
“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.
Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i.
Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà.
Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.
“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.
Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.
“ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.
Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ, tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ.
Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”
Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni.
Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò.
Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.
Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.
Ní àárín gbogbo ẹ̀yà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún un,” ní Olúwa Olódùmarè wí.