2 Samuẹli 23:13-39
13
Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu.
14
Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà.
15
Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.”
16
Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá, òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa.
17
Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe.
18
Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
19
Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.
20
Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.
21
Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.
22
Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.
23
Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.
24
Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà: Asaheli arákùnrin Joabu sì Jásí Elhanani ọmọ Dodo ti Bẹtilẹhẹmu;
25
Ṣamma ará Haroditi, Elika ará Harodi.
26
Helesi ará Palti, Ira ọmọ Ikẹsi ará Tekoa;
27
Abieseri ará Anatoti, Sibekai ará Huṣati;
28
Salmoni ará Ahohi, Maharai ará Netofa;
29
Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa, Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini;
30
Benaiah ará Piratoni, Hiddai ti àfonífojì Gaaṣi,
31
Abi-Alboni ará Arbati, Asmafeti Barhumiti;
32
Eliaba ará Ṣaalboni, àwọn ọmọ Jaṣeni, Jonatani;
33
ọmọ Ṣamma ará Harari, Ahiamu ọmọ Ṣarari ará Harari;
34
Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ará Maakati, Eliamu ọmọ Ahitofeli ará Giloni;
35
Hesro ará Karmeli, Paarai ará Arba;
36
Igali ọmọ Natani ti Soba, Bani ará Gadi;
37
Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beeroti, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah;
38
Ira ará Itri, Garebu ará Itri.
39
Uriah ará Hiti. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.
Settings