Skip to content
2 Samuẹli 23:18-23

2 Samuẹli 23:18-23

18
Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
19
Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó sì jẹ́ olórí fún wọn, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.
20
Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì.
21
Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò, ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.
22
Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.
23
Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options