2 Samuẹli 23:8-12
8
Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.
9
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò.
10
Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.
11
Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili, àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini.
12
Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá.
Settings