2 Samuẹli 23:1-7
1
Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé,
2
“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.
3
Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
4
Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’
5
“Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà.
6
Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.
7
Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.”
Settings