Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Young Men

347 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

  2. Ẹni tí ó ṣìkà sí baba rẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde òun ni ọmọ tí ń ṣe ìtìjú, tí ó sì mú ẹ̀gàn wá.

  3. Ọmọ mi, dẹ́kun láti tẹ́tí sí ẹ̀kọ́, tí í mú ni ṣìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀-ìmọ̀.

  4. Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó.

  5. Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.

  6. Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́.

  7. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù Olúwa, ní ọjọ́ gbogbo.

  8. Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́; ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.

  9. Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n, kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́.

  10. Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí; àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun;

  11. nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

  12. Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó.

  13. Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á; ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye.

  14. Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi: ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n, yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀.

  15. Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀, sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn.

  16. Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi.

  17. Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni; àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni.

  18. Òun á sì ba ní bùba bí olè, a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn.

  19. Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́? Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

  20. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

  21. Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n, nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago, tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

  22. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

  23. Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.

  24. Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun, tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

  25. Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí; wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀: nígbà wo ni èmi ó jí? Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”