- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Young Men
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí, ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.’
“Ó sì wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ ń bẹ lọ́dọ̀ mi, ohun gbogbo tí mo sì ní, tìrẹ ni.
Ó yẹ kí a ṣe àríyá kí a sì yọ̀: nítorí arákùnrin rẹ yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i.’ ”
Ìjòyè kan sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, wí pé, “Olùkọ́ rere, kín ni èmi ó ṣe tí èmi ó fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
Jesu wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí bí kò ṣe ẹnìkan, èyí sì ni Ọlọ́run.
Ìwọ mọ̀ àwọn òfin: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”
Ó sì wí pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti pamọ́ láti ìgbà èwe mi wá.”
Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.
Máa sá fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èwe, sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá.
Ìbéèrè òmùgọ̀ àti aláìní ẹ̀kọ́ nínú ni kí o kọ̀, bí o ti mọ̀ pe wọn máa dá ìjà sílẹ̀.
Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu.
Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao;
o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe, Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n, nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba, nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin, nítorí tí ẹ̀yin ni agbára, tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín, tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.
Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.
Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.