Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Young Men

347 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.

  3. (Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;

  4. bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)

  5. Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé,

  6. “Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.

  7. Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!

  8. Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.

  9. Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi bí i òjìá, aloe àti kinamoni.

  10. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

  11. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.

  12. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

  13. Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

  14. Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.

  15. Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

  16. Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.

  17. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.

  18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.

  19. Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú, tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.

  20. Àwọn òwe Solomoni. Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

  21. Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.

  22. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

  23. Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

  24. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.

  25. Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.