Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Travellers

110 ẹsẹ · 39 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.”

  2. Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn.

  3. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”

  4. Nígbà tí ó wòkè ó rí arìnrìn-àjò náà ní gbọ̀ngàn ìlú náà, ọkùnrin arúgbó yìí bi í léèrè pé, “Níbo ni ò ń lọ? Níbo ni o ti ń bọ̀?”

  5. Àwa ní koríko àti oúnjẹ tó tó fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa àti oúnjẹ àti wáìnì fún àwa ìránṣẹ́ rẹ—èmi, ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú wa. A ò ṣe aláìní ohun kankan.”

  6. Ọkùnrin arúgbó náà sì wí pé. “Àlàáfíà fún ọ, bí ó ti wù kí ó rí, èmi yóò pèsè gbogbo ohun tí o nílò, kìkì pé kí ìwọ má ṣe sun ní ìgboro.”

  7. Òun sì mú wa sí ilé rẹ̀, ó ń bọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wẹ ẹsẹ̀ wọn, àwọn àlejò náà jẹ, wọ́n mu.

  8. Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.

  9. Dafidi sì gbọ́ ní aginjù pé Nabali ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀.

  10. Dafidi sì rán ọmọkùnrin mẹ́wàá, Dafidi sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Karmeli, kí ẹ sì tọ Nabali lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.

  11. Báyìí ni ẹ ó sì wí fún ẹni tí ó wà ni ìrora pé, ‘Àlàáfíà fún ọ! Àlàáfíà fún ohun gbogbo tí ìwọ ní!

  12. “ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ. Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli.

  13. Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojúrere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àsè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àti fún Dafidi ọmọ rẹ.’ ”

  14. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì lọ, wọ́n sì sọ fún Nabali gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì sinmi.

  15. Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.

  16. Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?”

  17. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

  18. Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù.

  19. Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

  20. Dafidi sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, tiwọn kò lè tọ́ Dafidi lẹ́yìn mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni àfonífojì Besori: wọ́n sì lọ pàdé Dafidi, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dafidi sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn.

  21. Barsillai ará Gileadi sì sọ̀kalẹ̀ láti Rogelimu wá, ó sì bá ọba gòkè odò Jordani, láti ṣe ìkẹ́ rẹ̀ sí ìkọjá odò Jordani.

  22. Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.

  23. Agbára Olúwa sì ń bẹ lára Elijah; ó sì di àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ, ó sì sáré níwájú Ahabu títí dé Jesreeli.

  24. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli jáde lọ pẹ̀lú ọba Juda àti ọba Edomu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ-ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  25. Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.”