Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Serpents

38 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

  2. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí, “Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ! Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́, ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

  3. Èmi yóò sì fi ọ̀tá sí àárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà; òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

  4. Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn.

  5. Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.” Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un.

  6. “Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.”

  7. Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.

  8. Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú.

  9. Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

  10. Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

  11. Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.

  12. Èmi yóò mú wọn gbẹ, ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n. Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

  13. Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.

  14. Oró wọn dàbí oró ejò, wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,

  15. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.

  16. nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.

  17. Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò, a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

  18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.

  19. Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

  20. Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.

  21. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì; Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.

  22. Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.

  23. Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.

  24. “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.

  25. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.