Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Serpents: Of the devil
Àwọn ẹsẹ nípa Of the devil
Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”
Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi.
A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ni Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.
O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.